6. Gbogbo ọkunrin, lára àwọn alufaa lè jẹ ninu rẹ̀, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
7. “Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi dàbí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, òfin kan ṣoṣo ni ó de oríṣìí ẹbọ mejeeji: òfin náà sì ni pé alufaa tí ó fi ṣe ètùtù ni ó ni ẹbọ náà.
8. Alufaa tí ó bá rú ẹbọ sísun fún eniyan ni ó ni awọ ẹran ẹbọ sísun náà.
9. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a yan ati gbogbo èyí tí a sè ninu apẹ tabi ninu àwo pẹrẹsẹ jẹ́ ti alufaa tí ó fi wọ́n rúbọ.
10. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò tabi tí ó jẹ́ ìyẹ̀fun, yóo wà fún àwọn ọmọ Aaroni bákan náà.
11. “Èyí ni òfin ẹbọ alaafia, tí eniyan lè rú sí OLUWA.
12. Tí ó bá rú u fún ìdúpẹ́, yóo rú u pẹlu àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, tí a fi òróró pò, ati àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró lé lórí, pẹlu àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná ṣe, tí a fi òróró pò dáradára.
13. Ẹni tí ó bá rú ẹbọ alaafia fún ìdúpẹ́ yóo mú ẹbọ rẹ̀ wá pẹlu àkàrà tí ó ní ìwúkàrà.
14. Kí ó yọ àkàrà kọ̀ọ̀kan kúrò lára ẹbọ kọ̀ọ̀kan, kí ó fi rúbọ sí OLUWA; yóo jẹ́ ti alufaa tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ alaafia náà sára pẹpẹ.
15. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji.