14. “Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ohun jíjẹ. Àwọn ọmọ Aaroni ni yóo máa rúbọ náà níwájú pẹpẹ, níwájú OLUWA.
15. Ọ̀kan ninu wọn yóo bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀, yóo sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA ni.
16. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo jẹ ìyókù, láì fi ìwúkàrà sí i. Ibi mímọ́ kan ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni wọ́n ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́.