1. OLUWA sọ fun Mose
2. pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹnìkan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pataki kan láti fi odidi eniyan fún OLUWA, tí kò bá lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, iye tí ó níláti san nìyí:
3. Fún ọkunrin tí ó jẹ́ ẹni ogún ọdún sí ọgọta ọdún, yóo san aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ìwọ̀n ṣekeli ibi mímọ́ ni kí wọ́n fi wọn owó náà.
4. Bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹni náà yóo san ọgbọ̀n ìwọ̀n ṣekeli.
5. Bí ó bá jẹ́ ọkunrin, tí ó jẹ́ ẹni ọdún marun-un sí ogun ọdún, yóo san ogun ìwọ̀n ṣekeli; bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ṣekeli mẹ́wàá.
6. Bí ó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọmọ ọdún marun-un, tí ó sì jẹ́ ọkunrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un, bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka mẹta.
7. Bí ẹni náà bá tó ẹni ọgọta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ ọkunrin, kí ó san ṣekeli mẹẹdogun, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin, kí ó san Ṣekeli mẹ́wàá.