Lefitiku 25:23-32 BIBELI MIMỌ (BM)

23. “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi.

24. “Ninu gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìkáwọ́ yín, ẹ gbọdọ̀ fi ààyè sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ra ilẹ̀ pada.

25. Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada.

26. Bí ẹni náà kò bá ní ẹbí tí ó lè ra ilẹ̀ náà pada, ṣugbọn ní ọjọ́ iwájú, tí nǹkan bá ń lọ déédé fún un, tí ó sì ní agbára láti ra ilẹ̀ náà pada,

27. kí ó ṣírò iye ọdún tí ó ti tà á, kí ó sì san iye owó tí ó bá kù pada fún ẹni tí ó ta ilẹ̀ náà fún, lẹ́yìn náà kí ó pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

28. Ṣugbọn bí kò bá ní agbára tó láti ra ilẹ̀ náà pada fúnra rẹ̀, ilẹ̀ náà yóo wà ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á lọ́wọ́ rẹ̀ títí di ọdún jubili. Ní ọdún jubili, ẹni tí ó ra ilẹ̀ náà yóo dá a pada, ẹni tí ó ni ín yóo sì pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

29. “Bí ẹnìkan bá ta ilé kan ninu ìlú olódi, ó lè rà á pada láàrin ọdún kan lẹ́yìn tí ó ti tà á.

30. Bí ẹni náà kò bá ra ilé náà pada láàrin ọdún kan, ilé yóo di ti ẹni tí ó rà á títí lae ati ti arọmọdọmọ rẹ̀; kò ní jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí ọdún jubili tilẹ̀ dé.

31. Ṣugbọn a óo ka àwọn ilé tí wọ́n wà ní àwọn ìlú tí kò ní odi pọ̀ mọ́ ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ wọn lé lórí. Ẹni tí ó ta ilẹ̀ lé rà wọ́n pada, ẹni tí ó rà á sì níláti jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ nígbà tí ọdún jubili bá dé.

32. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi lè ra gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà ní ààrin ìlú wọn pada nígbàkúùgbà.

Lefitiku 25