21. Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta.
22. Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ.
23. “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi.
24. “Ninu gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìkáwọ́ yín, ẹ gbọdọ̀ fi ààyè sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ra ilẹ̀ pada.
25. Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada.