Lefitiku 25:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ lórí òkè Sinai, ó ní,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, àkókò ìyàsọ́tọ̀ kan gbọdọ̀ wà fún ilẹ̀ náà tí yóo jẹ́ àkókò ìsinmi fún OLUWA.

3. Ọdún mẹfa ni kí ẹ máa fi gbin èso sinu oko yín, ọdún mẹfa náà sì ni kí ẹ máa fi tọ́jú ọgbà àjàrà yín, tí ẹ óo sì máa fi kórè èso rẹ̀.

4. Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín.

5. Ohunkohun tí ó bá dá hù fún ara rẹ̀ ninu oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ kórè èso tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà yín tí ẹ kò tọ́jú. Ọdún náà gbọdọ̀ jẹ́ ọdún ìsinmi fún ilẹ̀.

6. Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé,

7. ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ yín, gbogbo èso ilẹ̀ náà yóo sì wà fún jíjẹ.

8. “Ẹ ka ìsinmi ọdún keje keje yìí lọ́nà meje, kí ọdún keje náà fi jẹ́ ọdún mọkandinlaadọta.

9. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹwaa oṣù keje tíí ṣe ọjọ́ ètùtù, ẹ óo rán ọkunrin kan kí ó lọ fọn fèrè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín.

Lefitiku 25