Lefitiku 25:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ lórí òkè Sinai, ó ní,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, àkókò ìyàsọ́tọ̀ kan gbọdọ̀ wà fún ilẹ̀ náà tí yóo jẹ́ àkókò ìsinmi fún OLUWA.

3. Ọdún mẹfa ni kí ẹ máa fi gbin èso sinu oko yín, ọdún mẹfa náà sì ni kí ẹ máa fi tọ́jú ọgbà àjàrà yín, tí ẹ óo sì máa fi kórè èso rẹ̀.

4. Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín.

5. Ohunkohun tí ó bá dá hù fún ara rẹ̀ ninu oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ kórè èso tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà yín tí ẹ kò tọ́jú. Ọdún náà gbọdọ̀ jẹ́ ọdún ìsinmi fún ilẹ̀.

6. Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé,

7. ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ yín, gbogbo èso ilẹ̀ náà yóo sì wà fún jíjẹ.

Lefitiku 25