5. “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni kí ẹ máa ṣe àjọ ìrékọjá OLUWA.
6. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kan náà sì ni àjọ àìwúkàrà OLUWA. Ọjọ́ meje gbáko ni ẹ gbọdọ̀ fi máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.
7. Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára.
8. Ṣugbọn, ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA fún ọjọ́ meje náà, ọjọ́ àpèjọ mímọ́ ni ọjọ́ keje yóo jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó lágbára.”
9. OLUWA tún rán Mose pé kí ó
10. sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, tí ẹ bá sì ń kórè nǹkan inú rẹ̀, ẹ níláti gbé ìtí ọkà kan lára àkọ́so oko yín tọ alufaa lọ.
11. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keji, lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, alufaa yóo fi ìtí ọkà náà rú ẹbọ fífì níwájú OLUWA, kí ẹ lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
12. Ní ọjọ́ tí ẹ bá ń fi ìtí ọkà yín rú ẹbọ fífì, kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ aguntan ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.