4. Kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́, nítorí olórí ló jẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
5. “Alufaa kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ débi pé kí ó fá irun rẹ̀, tabi kí ó gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n rẹ̀ tabi kí ó fi abẹ ya ara rẹ̀.
6. Wọ́n níláti jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun wọn, wọn kò sì gbọdọ̀ sọ orúkọ Ọlọrun wọn di aláìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA; èyí tíí ṣe oúnjẹ Ọlọrun wọn, nítorí náà wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.
7. Nítorí pé alufaa jẹ́ ẹni mímọ́ fún Ọlọrun rẹ̀, kò gbọdọ̀ gbé aṣẹ́wó ní iyawo, tabi obinrin tí ó ti di aláìmọ́, tabi obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.
8. Ẹ gbọdọ̀ ka alufaa sí ẹni mímọ́, nítorí òun ni ó ń rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun yín. Ó níláti jẹ́ ẹni mímọ́ fun yín, nítorí pé èmi OLUWA tí mo yà yín sí mímọ́ jẹ́ mímọ́.
9. Ọmọ alufaa lobinrin, tí ó bá sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa ṣíṣe àgbèrè káàkiri, sọ baba rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí náà sísun ni kí ẹ dáná sun ọmọ náà.
10. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ alufaa àgbà láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n ti ta òróró sí lórí láti yà á sọ́tọ̀, kí ó lè máa wọ àwọn aṣọ mímọ́, kò gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ rí játijàti; kò sì gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya, láti fi hàn pé ó ń ṣọ̀fọ̀.
11. Kò gbọdọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n bá tẹ́ òkú sí, tabi kí ó sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú baba rẹ̀ tabi ti ìyá rẹ̀.
12. Kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ninu ibi mímọ́ náà, tabi kí ó sọ ibi mímọ́ Ọlọrun rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí pé, òróró ìyàsímímọ́ Ọlọrun rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Èmi ni OLUWA.
13. Obinrin tí kò bá tíì mọ ọkunrin rí ni ó gbọdọ̀ fẹ́ níyàwó.