15. Kí ó má baà sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìmọ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé èmi ni OLUWA, tí mo sọ ọ́ di mímọ́.”
16. OLUWA sọ fún Mose,
17. kí ó sọ fún Aaroni pé, “Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ rẹ̀ tí ó bá ní àbùkù kankan kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀.
18. Nítorí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ, kì báà jẹ́ afọ́jú, tabi arọ, ẹni tí ijamba bá bà lójú jẹ́, tabi tí apá tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn ju ekeji lọ,
19. tabi tí ijamba bá ṣe ní ọwọ́ kan tabi ẹsẹ̀ kan,
20. tabi abuké, aràrá, tabi ẹni tí kò ríran dáradára, tabi ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀yi tabi ìpẹ́pẹ́, tabi ẹni tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà.