Lefitiku 20:20-22 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ.

21. Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ.

22. “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ kíyèsí gbogbo àwọn ìlànà mi ati àwọn òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ tí mò ń ko yín lọ má baà tì yín jáde.

Lefitiku 20