8. O kò gbọdọ̀ bá aya baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni.
9. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin rẹ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lobinrin, tabi ọmọ baba rẹ lobinrin, kì báà jẹ́ pé ilé ni wọ́n bí i sí tabi ìdálẹ̀.
10. O kò gbọdọ̀ bá ọmọ ọmọ rẹ lobinrin lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ obinrin tabi ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin, nítorí ohun ìtìjú ni ó jẹ́ fún ọ, nítorí pé, ìhòòhò wọn jẹ́ ìhòòhò rẹ.
11. O kò gbọdọ̀ bá ọmọ tí aya baba rẹ bá bí fún baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, arabinrin rẹ ni.
12. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí baba rẹ ni ó jẹ́.
13. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí ìyá rẹ ni ó jẹ́.
14. O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún ọ.