1. OLUWA ní kí Mose,
2. sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
3. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí mò ń ko yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìlànà wọn.
4. Àwọn òfin mi ni ẹ gbọdọ̀ pamọ́, àwọn ìlànà mi sì ni ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé, tí ẹ sì gbọdọ̀ máa tọ̀. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
5. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé ìlànà mi kí ẹ sì máa pa àwọn òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ń pa wọ́n mọ́ yóo wà láàyè. Èmi ni OLUWA.
6. “Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ tọ ìbátan rẹ̀ lọ láti bá a lòpọ̀. Èmi ni OLUWA.
7. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ bá ìyá rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé, bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni, ìyá rẹ ni, o kò gbọdọ̀ tú ìyá rẹ síhòòhò.