Lefitiku 15:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ẹni náà, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

8. Bí ẹnikẹ́ni tí nǹkan dà lára rẹ̀ bá tutọ́ sí ara ẹni tí ó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

9. Gàárì ẹṣin tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi gun ẹṣin di aláìmọ́.

10. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kan ohunkohun, ninu ohun tí ó fi jókòó di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ru èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí ẹni náà fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; olúwarẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

11. Ẹni tí nǹkan ọkunrin dà lára rẹ̀ yìí gbọdọ̀ fọ ọwọ́ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ẹni náà bá fi ọwọ́ kàn, kí ó tó fọ ọwọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

12. Kí wọ́n fọ́ kòkò tí ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí bá fi ọwọ́ kàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun èlò onígi tí ó bá fọwọ́ kàn, wọ́n gbọdọ̀ fọ̀ wọn.

Lefitiku 15