26. Ibùsùn tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, ní gbogbo ọjọ́ tí nǹkan yìí bá fi ń dà lára rẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́; ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
27. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
28. Ṣugbọn nígbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dá, kí ó ka ọjọ́ meje lẹ́yìn ọjọ́ náà; lẹ́yìn náà, ó di mímọ́.
29. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
30. Kí alufaa fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi ekeji rú ẹbọ sísun, kí ó ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ohun àìmọ́ tí ó jáde lára rẹ̀.
31. “Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn eniyan Israẹli kúrò lára àìmọ́ wọn, kí wọ́n má baà sọ ibi mímọ́ tí ó wà láàrin wọn di aláìmọ́, kí wọ́n sì kú.”
32. Òfin yìí ni ó jẹmọ́ ti ọkunrin tí nǹkankan tabi nǹkan ọkunrin bá dà lára rẹ̀, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́;
33. ati obinrin tí ó ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ tabi tí nǹkan oṣù di àìsàn sí lára; ẹnikẹ́ni tí nǹkan bá sá ti ń dà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, ati ọkunrin tí ó bá bá obinrin tí ó jẹ́ aláìmọ́ lòpọ̀.