Lefitiku 15:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní kí Mose ati Aaroni

2. sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Nígbà tí nǹkan bá dà jáde lára ọkunrin, nǹkan tí ó jáde lára rẹ̀ yìí jẹ́ aláìmọ́.

3. Èyí sì ni òfin tí ó jẹmọ́ àìmọ́ rẹ̀, nítorí nǹkan tí ó ti ara rẹ̀ jáde; kì báà jẹ́ pé ó ń dà lọ́wọ́ lọ́wọ́, tabi ó ti dà tán, nǹkan tí ó dà yìí jẹ́ àìmọ́ lára rẹ̀.

4. Ibùsùn tí ẹni náà bá dùbúlẹ̀ lé lórí di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ pẹlu.

5. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkohun tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi jókòó, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

7. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ẹni náà, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

8. Bí ẹnikẹ́ni tí nǹkan dà lára rẹ̀ bá tutọ́ sí ara ẹni tí ó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

Lefitiku 15