Lefitiku 11:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA rán Mose ati Aaroni pé

2. kí wọ́n sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn ẹran tí wọ́n lè jẹ lára àwọn ẹran tí wọ́n wà láyé nìwọ̀nyí:

3. Àwọn ẹran tí wọ́n bá ya pátákò ẹsẹ̀, àwọn tí ẹsẹ̀ wọ́n là ati àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ.

4. Ninu àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ tabi tí pátákò ẹsẹ̀ wọ́n yà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn wọnyi: ràkúnmí, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

5. Ati gara nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

6. Ati ehoro, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

7. Ati ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ yà, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì yà, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

8. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn, aláìmọ́ ni wọ́n.

9. “Ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ àwọn wọnyi: gbogbo ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, kì báà jẹ́ èyí tí ó ń gbé inú òkun tabi inú odò, ẹ lè jẹ wọ́n.

Lefitiku 11