1. OLUWA rán Mose ati Aaroni pé
2. kí wọ́n sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn ẹran tí wọ́n lè jẹ lára àwọn ẹran tí wọ́n wà láyé nìwọ̀nyí:
3. Àwọn ẹran tí wọ́n bá ya pátákò ẹsẹ̀, àwọn tí ẹsẹ̀ wọ́n là ati àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ.
4. Ninu àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ tabi tí pátákò ẹsẹ̀ wọ́n yà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn wọnyi: ràkúnmí, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.
5. Ati gara nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.