3. “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.
4. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.
5. Kí ó pa akọ mààlúù náà níbẹ̀, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá siwaju OLUWA, kí wọn da ẹ̀jẹ̀ náà yíká ara pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
6. Mú ẹran náà, kí o bó awọ rẹ̀, kí o sì gé e sí wẹ́wẹ́;
7. kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to igi sórí pẹpẹ náà kí wọ́n sì dáná sí i.