Kronika Kinni 9:14-18 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣemaaya ọmọ Haṣihubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, lára àwọn ọmọ Merari;

15. ati Bakibakari, Hereṣi, Galali ati Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sikiri, ọmọ Asafu,

16. ati Ọbadaya ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Galali, ọmọ Jẹdutumu, ati Berekaya ọmọ Asa, ọmọ Elikana, tí ń gbé agbègbè tí àwọn ọmọ Netofa wà.

17. Àwọn aṣọ́nà Tẹmpili nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Akubu, Talimoni, Ahimani, ati àwọn eniyan wọn; (Ṣalumu ni olórí wọn).

18. Wọ́n ń ṣọ́ apá ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn ilé ọba. Àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àgọ́ àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀.

Kronika Kinni 9