Kronika Kinni 8:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu.

9. Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami,

10. Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.

11. Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.

12. Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.

13. Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;

Kronika Kinni 8