1. Bẹnjamini bí ọmọkunrin marun-un, Bela ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Aṣibeli,
2. lẹ́yìn rẹ̀, Ahara, lẹ́yìn rẹ̀, Nohahi, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni, Rafa.
3. Àwọn ọmọ Bela ni: Adari, Gera, ati Abihudi,
4. Abiṣua, Naamani, ati Ahoa,
5. Gera, Ṣefufani, ati Huramu.
6. Àwọn wọnyi ni ìran Ehudu: (Àwọn baálé baálé ninu ìran Geba, tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí ìlú Manahati):
7. Naamani, Ahija ati Gera, tí ń jẹ́ Hegilamu, baba Usa, ati Ahihudu.
8. Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu.
9. Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami,
10. Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.
11. Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.
12. Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.