4. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé ìdílé, àwọn jagunjagun tí wọ́n ní tó ẹgbaa mejidinlogun (36,000) kún ara wọn, ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí; nítorí wọ́n ní ọpọlọpọ iyawo ati ọmọ.
5. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu àwọn ìbátan wọn ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogoji ó lé ẹgbẹrun (87,000).
6. Àwọn mẹta ni ọmọ Bẹnjamini: Bela, Bekeri, ati Jediaeli.
7. Bela bí ọmọ marun-un: Esiboni, Usi, Usieli, Jerimotu ati Iri. Àwọn ni baálé ìdílé wọn, wọ́n sì jẹ́ akọni jagunjagun. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu ìdílé wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ati mẹrinlelọgbọn (22,034).
8. Bekeri bí ọmọ mẹsan-an: Semira, Joaṣi, ati Elieseri; Elioenai, Omiri, ati Jeremotu; Abija, Anatoti, ati Alemeti.
9. Àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé, àwọn baálé baálé ní ilé baba wọn, tí wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati igba (20,200).