1. Àwọn mẹrin ni ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu ati Ṣimironi.
2. Àwọn ọmọ Tola ni: Usi, Refaaya, Jerieli, Jahimai, Ibisamu ati Ṣemueli, àwọn ni baálé ninu ìdílé Tola, baba wọn, akikanju jagunjagun ni wọ́n ní àkókò wọn. Ní ayé Dafidi ọba, àwọn akikanju jagunjagun wọnyi jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹta (22,600).
3. Usi ni ó bí Isiraya. Isiraya sì bí ọmọ mẹrin: Mikaeli, Ọbadaya, Joẹli, ati Iṣaya; wọ́n di marun-un, àwọn maraarun ni wọ́n sì jẹ́ ìjòyè.
4. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé ìdílé, àwọn jagunjagun tí wọ́n ní tó ẹgbaa mejidinlogun (36,000) kún ara wọn, ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí; nítorí wọ́n ní ọpọlọpọ iyawo ati ọmọ.
5. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu àwọn ìbátan wọn ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogoji ó lé ẹgbẹrun (87,000).
6. Àwọn mẹta ni ọmọ Bẹnjamini: Bela, Bekeri, ati Jediaeli.
7. Bela bí ọmọ marun-un: Esiboni, Usi, Usieli, Jerimotu ati Iri. Àwọn ni baálé ìdílé wọn, wọ́n sì jẹ́ akọni jagunjagun. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu ìdílé wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ati mẹrinlelọgbọn (22,034).