45. ọmọ Haṣabaya, ọmọ Amasaya, ọmọ Hilikaya;
46. ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri;
47. ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
48. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi, arakunrin wọn yòókù láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó kù ninu ilé Ọlọrun.
49. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀.
50. Àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí: Eleasari baba Finehasi, baba Abiṣua;
51. baba Buki, baba Usi, baba Serahaya;
52. baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu;
53. baba Sadoku, baba Ahimaasi.
54. Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi.
55. Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká,
56. ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká.