6. Naara bí ọmọ mẹrin fún un: Ahusamu, Heferi, Temeni, ati Haahaṣitari.
7. Hela bí ọmọ mẹta fún un: Sereti, Iṣari, ati Etinani.
8. Kosi ni baba Anubi ati Sobeba. Òun ni baba ńlá àwọn ìdílé Ahaheli, ọmọ Harumu.
9. Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i.
10. Jabesi gbadura sí Ọlọrun Israẹli pé, “Ọlọrun jọ̀wọ́ bukun mi, sì jẹ́ kí ilẹ̀ ìní mi pọ̀ sí i. Wà pẹlu mi, pa mí mọ́ kúrò ninu ewu, má jẹ́ kí jamba ṣe mí!” Ọlọrun sì ṣe ohun tí ó fẹ́ fún un.