15. Balogun tí ó wà fún oṣù kejila ni Helidai ará Netofati, láti inú ìran Otinieli; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
16. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí, láti inú ẹ̀yà Reubẹni: Elieseri, ọmọ Sikiri ni olórí patapata. Láti inú ẹ̀yà Simeoni: Ṣefataya, ọmọ Maaka.
17. Láti inú ẹ̀yà Lefi: Haṣabaya, ọmọ Kemueli; láti ìdílé Aaroni: Sadoku;
18. láti inú ẹ̀yà Juda: Elihu, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi; láti inú ẹ̀yà Isakari: Omiri, ọmọ Mikaeli;
19. láti inú ẹ̀yà Sebuluni: Iṣimaya, ọmọ Ọbadaya; láti inú ẹ̀yà Nafutali: Jeremotu, ọmọ Asirieli;