Kronika Kinni 26:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí a ti ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà nìwọ̀nyí: Meṣelemaya, ọmọ Kore, ní ìdílé Asafu, ninu ìran Kora.

2. Meṣelemaya bí ọmọ meje, orúkọ wọn nìyí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, Sakaraya ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Jediaeli, Sebadaya, ati Jatinieli;

3. Elamu, Jehohanani ati Eliehoenai.

4. Ọmọ mẹjọ ni Obedi Edomu bí nítorí pé Ọlọrun bukun un. Orúkọ àwọn ọmọ náà nìyí, bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí: Ṣemaaya, Jehosabadi, ati Joa; Sakari, ati Netaneli;

5. Amieli, Isakari, ati Peuletai.

6. Ṣemaaya, àkọ́bí Obedi Edomu, bí ọmọ mẹfa, àwọn ni olórí ninu ìdílé wọn nítorí pé alágbára eniyan ni wọ́n.

7. Orúkọ wọn ni: Otini, Refaeli, Obedi, ati Elisabadi, ati àwọn arakunrin wọn, Elihu ati Semakaya, tí wọ́n jẹ́ alágbára eniyan.

8. Gbogbo àwọn arọmọdọmọ Obedi Edomu, ati àwọn ọmọ wọn, pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí wọ́n yẹ láti ṣiṣẹ́ jẹ́ mejilelọgọta.

9. Àwọn ọmọ Meṣelemaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí wọ́n lágbára jẹ́ mejidinlogun.

Kronika Kinni 26