Kronika Kinni 25:8-27 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi mọ iṣẹ́ olukuluku; ati kékeré ati àgbà, ati olùkọ́ ati akẹ́kọ̀ọ́.

9. Gègé kinni tí wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé Asafu mú Josẹfu; ekeji mú Gedalaya, òun ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ́ mejila.

10. Ẹkẹta mú Sakuri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

11. Ẹkẹrin mú Isiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

12. Ẹkarun-un mú Netanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

13. Ẹkẹfa mú Bukaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

14. Ekeje mú Jeṣarela, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

15. Ẹkẹjọ mú Jeṣaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

16. Ẹkẹsan-an mú Matanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

17. Ẹkẹwaa mú Ṣimei, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

18. Ikọkanla mú Asareli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

19. Ekejila mú Haṣabaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

20. Ẹkẹtala mú Ṣubaeli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

21. Ẹkẹrinla mú Matitaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

22. Ẹkẹẹdogun mú Jeremotu, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

23. Ẹkẹrindinlogun mu Hananaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

24. Ẹkẹtadinlogun mú Joṣibekaṣa, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

25. Ekejidinlogun mú Hanani, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

26. Ikọkandinlogun mú Maloti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

27. Gègé ogún mú Eliata, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

Kronika Kinni 25