4. Dafidi fún ẹgbaa mejila (24,000) ninu wọn ní iṣẹ́ ninu tẹmpili; ó ní kí ẹgbaata (6,000) máa ṣe àkọsílẹ̀ ati ìdájọ́ àwọn eniyan,
5. kí ẹgbaaji (4,000) máa ṣọ́nà, kí ẹgbaaji (4,000) sì máa yin OLUWA pẹlu oríṣìíríṣìí ohun èlò orin tí ọba pèsè.
6. Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari.
7. Àwọn ọmọ Geriṣomu jẹ́ meji: Ladani ati Ṣimei;
8. Àwọn ọmọ Ladani jẹ́ mẹta: Jeieli tí ó jẹ́ olórí, Setamu ati Joẹli.