Kronika Kinni 23:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri.

16. Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu.

17. Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀.

18. Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀.

19. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu.

20. Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya.

21. Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi,

22. Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn.

Kronika Kinni 23