Kronika Kinni 22:7-10 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó ní, “Ọmọ mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili kan fún orúkọ OLUWA Ọlọrun mi,

8. ṣugbọn OLUWA sọ fún mi pé mo ti ta ọpọlọpọ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, mo sì ti ja ọpọlọpọ ogun; nítorí ọpọlọpọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà, òun kò ní gbà pé kí n kọ́ tẹmpili òun.

9. OLUWA ní n óo bí ọmọkunrin kan tí ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ ìjọba alaafia, ó ní òun óo fún un ní alaafia, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíká kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu. Solomoni ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. Ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo wà ní alaafia ati àìléwu.

10. Ó ní ọmọ náà ni yóo kọ́ ilé fún òun. Yóo jẹ́ ọmọ òun, òun náà yóo sì jẹ́ baba rẹ̀. Ó ní òun óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Israẹli títí lae.

Kronika Kinni 22