Kronika Kinni 21:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Satani fẹ́ ta jamba fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí náà ó gbó Dafidi láyà láti kà wọ́n.

2. Dafidi sọ fún Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pé, “Ẹ lọ ka àwọn ọmọ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, kí ẹ wá fún mi lábọ̀, kí n lè mọ iye wọn.”

3. Ṣugbọn Joabu dáhùn pé, “Kí Ọlọrun jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un, ju iye tí wọ́n jẹ́ nisinsinyii lọ! Kabiyesi, ṣebí abẹ́ ìwọ oluwa mi ni gbogbo wọn wà? Kí ló wá dé tí o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló dé tí o fi fẹ́ mú àwọn ọmọ Israẹli jẹ̀bi?”

4. Ṣugbọn ti ọba ni ó ṣẹ, Joabu bá lọ kà wọ́n jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì pada wá sí Jerusalẹmu.

Kronika Kinni 21