Kronika Kinni 20:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí àkókò òtútù kọjá, ní àkókò tí àwọn ọba máa ń lọ jagun, Joabu gbógun ti ilẹ̀ Amoni; wọ́n dó ti ìlú Raba. Ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu gbógun ti Raba, ó sì ṣẹgun rẹ̀.

2. Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, ó sì rí i pé adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, òkúta olówó iyebíye kan sì wà lára rẹ̀; wọ́n bá fi dé Dafidi lórí. Dafidi sì tún kó ọpọlọpọ ìkógun mìíràn ninu ìlú náà.

3. Ó kó àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu ìlú náà, ó sì ń fi wọ́n ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́: Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn kan ń lo ọkọ́, àwọn mìíràn sì ń lo àáké. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe sí gbogbo àwọn ìlú Amoni. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀ bá pada sí Jerusalẹmu.

4. Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia.

5. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, Elihanani, ọmọ Jairi, pa Lahimi, arakunrin Goliati, ará Gati, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi tó òpó òfì ìhunṣọ.

Kronika Kinni 20