39. Asaraya ni ó bí Helesi, Helesi ni ó sì bí Eleasa.
40. Eleasa bí Sisimai, Sisimai bí Ṣalumu;
41. Ṣalumu bí Jekamaya, Jekamaya sì bí Eliṣama.
42. Àwọn ọmọ Kalebu, arakunrin Jerameeli, nìwọ̀nyí: Mareṣa, baba Sifi ni àkọ́bí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Heburoni.
43. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Kora, Tapua, Rekemu ati Ṣema.
44. Ṣema bí Rahamu, Rahamu bí Jokeamu, Rekemu sì bí Ṣamai.
45. Ṣamai ló bí Maoni, Maoni sì bí Betisuri.
46. Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi.
47. Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu.
48. Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana.