1. Nígbà tí ó yá, Nahaṣi, ọba àwọn ará Amoni kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
2. Dafidi ní, “N óo fi ìfẹ́ hàn sí Hanuni bí baba rẹ̀ ti fi ìfẹ́ hàn sí mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ kí i kú àṣẹ̀yìndè baba rẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ Dafidi bá lọ sọ́dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ Amoni láti bá a kẹ́dùn.
3. Ṣugbọn àwọn ìjòyè ilẹ̀ Amoni sọ fún ọba pé, “Ṣé o rò pé Dafidi ń bọ̀wọ̀ fún baba rẹ ni ó ṣe rán oníṣẹ́ láti wá bá ọ kẹ́dùn? Rárá o. Ó rán wọn láti wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni, kí ó baà lè ṣẹgun rẹ.”
4. Nítorí náà, Hanuni mú àwọn oníṣẹ́ Dafidi, ó fá irùngbọ̀n wọn, ó gé ẹ̀wù wọn ní ìbàdí, ó sì lé wọn jáde.