Kronika Kinni 18:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki.

12. Abiṣai, ọmọ Seruaya, ṣẹgun àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀, ó pa ẹgbaa mẹsan-an (18,000) ninu wọn.

13. Ó fi àwọn ọmọ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì di iranṣẹ Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

14. Dafidi jọba lórí gbogbo Israẹli, ó ń dá ẹjọ́ òtítọ́, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo àwọn eniyan.

15. Joabu, ọmọ Seruaya, ni Balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀.

16. Sadoku, ọmọ Ahitubu ati Ahimeleki ọmọ Abiatari ni alufaa.

17. Ṣafiṣa ni akọ̀wé ilé ẹjọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ní ń ṣe àkóso àwọn Kereti ati Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, àwọn ọmọ Dafidi lọkunrin ni wọ́n sì wà ní àwọn ipò tí ó ga ninu ìjọba rẹ̀.

Kronika Kinni 18