1. Ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, wọ́n sì pa ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Giliboa.
2. Ọwọ́ wọn tẹ Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n pa Jonatani, Abinadabu ati Malikiṣua.
3. Ogun gbóná janjan yí Saulu ká, àwọn tafàtafà rí i, wọ́n ta á lọ́fà, ó sì fara gbọgbẹ́,
4. Saulu ba sọ fún ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì gún mi pa, kí àwọn aláìkọlà ará Filistia má baà fi mi ṣẹ̀sín.” Ṣugbọn ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nítorí pe ẹ̀rù bà á; nítorí náà, Saulu fa idà ara rẹ̀ yọ, ó sì ṣubú lé e.
5. Nígbà tí ọdọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà ṣubú lé idà rẹ̀, ó sì kú.