Kronika Keji 9:22-26 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Solomoni ọba ní ọrọ̀ ati ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba yòókù lọ lórí ilẹ̀ ayé.

23. Gbogbo wọn ni wọ́n ń wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un. Fún ọpọlọpọ ọdún ni

24. ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn máa ń mú ẹ̀bùn wá fún un lọdọọdun, àwọn ẹ̀bùn bíi: ohun èlò fadaka, ati ti wúrà, aṣọ, ohun ìjà ogun, turari, ẹṣin, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

25. Solomoni ọba ní ẹgbaaji (4,000) ilé fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, ó ní ẹgbaafa (12,000) ẹlẹ́ṣin. Ó kó àwọn kan sí àwọn ìlú tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ó kó ìyókù sí Jerusalẹmu, níbi tí ọba ń gbé.

26. Solomoni jọba lórí àwọn ọba gbogbo, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati títí dé ààlà Ijipti.

Kronika Keji 9