Kronika Keji 5:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn alufaa gbé àpótí majẹmu OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu tẹmpili ní ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ àwọn ìyẹ́ kerubu.

8. Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀.

9. Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

10. Ohun kan ṣoṣo tí ó wà ninu àpótí náà ni tabili meji tí Mose kó sibẹ ní òkè Horebu, níbi tí Ọlọrun ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.

11. Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà.

Kronika Keji 5