12. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin,
13. àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé:“OLUWA ṣeun,ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.”Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA,
14. tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun.