1. Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).
2. Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½).
3. Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀.