Kronika Keji 35:23-27 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.”

24. Nítorí náà, wọ́n gbé e kúrò ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà tẹ́lẹ̀ sinu òmíràn, wọ́n sì gbé e lọ sí Jerusalẹmu. Ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalẹmu ṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀.

25. Wolii Jeremaya kọ orin arò fún Josaya ọba. Ó ti di àṣà ní Israẹli fún àwọn akọrin, lọkunrin ati lobinrin láti máa mẹ́nu ba Josaya nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń kọrin arò.

26. Àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ati iṣẹ́ rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA,

27. gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda.

Kronika Keji 35