Kronika Keji 30:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ogunlọ́gọ̀ eniyan, pataki jùlọ ọpọlọpọ ninu àwọn tí wọn wá láti Efuraimu, Manase, Isakari ati Sebuluni, kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, sibẹ wọ́n jẹ àsè Àjọ Ìrékọjá, ṣugbọn kì í ṣe ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn Hesekaya gbadura fún wọn pé: “Kí OLUWA rere dáríjì gbogbo àwọn

19. tí wọ́n fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni wọ́n fi jẹ àsè àjọ náà gẹ́gẹ́ bí òfin ìwẹ̀nùmọ́ ti ibi mímọ́.”

20. OLUWA gbọ́ adura Hesekaya, ó sì wo àwọn eniyan náà sàn.

21. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pa Àjọ Àìwúkàrà mọ́ fún ọjọ́ meje pẹlu ayọ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ń kọrin ìyìn sí OLUWA lojoojumọ pẹlu gbogbo agbára wọn.

Kronika Keji 30