Kronika Keji 27:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jotamu nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹrindinlogun. Jeruṣa, ọmọ Sadoku ni ìyá rẹ̀.

2. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bíi Usaya, baba rẹ̀; àfi pé òun kò lọ sun turari ninu tẹmpili OLUWA. Ṣugbọn àwọn eniyan ń bá ìwà burúkú wọn lọ.

3. Ó kọ́ ẹnu ọ̀nà òkè ilé OLUWA, ó sì tún ògiri Ofeli mọ.

4. Ó kọ́ àwọn ìlú ní agbègbè olókè Juda ó sì kọ́ ibi ààbò ati ilé-ìṣọ́ ninu igbó lára òkè.

Kronika Keji 27