Kronika Keji 23:6-9 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọnú ilé OLUWA, àfi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn lè wọlé nítorí pé wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ó kù gbọdọ̀ pa àṣẹ OLUWA mọ́.

7. Àwọn ọmọ Lefi yóo yí ọba ká láti ṣọ́ ọ, olukuluku yóo mú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n gbọdọ̀ wà pẹlu ọba níbikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wọnú ilé Ọlọrun, pípa ni kí ẹ pa á.”

8. Àwọn ọmọ Lefi ati gbogbo ọmọ Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada alufaa ti pàṣẹ fún wọn. Olukuluku kó àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi wá, wọ́n dúró pẹlu àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ipò wọn, nítorí Jehoiada alufaa kò jẹ́ kí wọ́n túká.

9. Jehoiada fún àwọn ọ̀gágun ní ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi tí wọ́n ti kó pamọ́ sinu ilé Ọlọrun.

Kronika Keji 23