19. Ó fi àwọn aṣọ́nà sí ẹnu àwọn ọ̀nà ilé OLUWA kí ẹnikẹ́ni tí kò bá mọ́ má baà wọlé.
20. Òun pẹlu àwọn balogun, àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn, àwọn gomina, ati gbogbo eniyan ilẹ̀ náà mú ọba láti ilé OLUWA, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà òkè wá sí ààfin, wọ́n sì fi í jókòó lórí ìtẹ́.
21. Inú gbogbo àwọn eniyan dùn, ìlú sì rọ̀ wọ̀ọ̀, nítorí pé wọ́n ti pa Atalaya.