3. Ìwà burúkú ni òun náà ń hù bíi ti Ahabu, nítorí pé ìyá rẹ̀ ní ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà ibi.
4. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, àwọn ará ilé Ahabu ni olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ni wọ́n fa ìṣubú rẹ̀.
5. Ìmọ̀ràn wọn ni ó tẹ̀lé tí ó fi pa ogun tirẹ̀ pọ̀ mọ́ ti Joramu, ọba Israẹli, láti bá Hasaeli ọba Siria jagun ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Siria sì ṣá Joramu lọ́gbẹ́ lójú ogun náà,
6. ó bá pada lọ sí ìlú Jesireeli láti wo ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun ní Rama nígbà tí ó ń bá Hasaeli ọba Siria jagun. Ahasaya, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli nítorí ara rẹ̀ tí kò yá.
7. Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run.
8. Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n.