18. Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀.
19. OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn.
20. Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’