6. Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa.
7. Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
8. Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.